Skip to main content

Ọ̀LẸ


Ọ̀lẹ yìí sùn lọ́ọrí
Ọ̀lẹ yìí sùn funfun
Ẹ wa bá mii jíń òle
Pé ojuúmó ti mọ́
Ẹ wa bá mi soofún òle
Pé òwúrò lọ jó ẹni a ríre
Ẹ bá mi soofún pé
Ẹni á gòkè láyé
Níí láti tepá mósé
Ẹni á wọ bàtà dídún láyé
Níí láti sẹ́ ara rẹ̀ lóorun
Emá gbàgbé láti wí fún pèé
Òsìn níí gbẹ̀yìn òle
Ẹni óò bá múra sí iṣé
Irú won níí di akóbàtà
Fún egbé
Ẹni óò bá múra sí isé
Irúu won níi di ògárá ọlọ́ṣà
Lọ́la
Ẹni ó bá mú ra sí isé
Irúu won níi di jàndùkú
Síìgboro
Ẹni ó bá mú ra sí isé
Irúu won níí di ẹni yẹpẹrẹ
Láwùjọ
Òlẹ!  Ìbá dára púpọ̀ kó o dìde
Lórí àkéte àìníkan ṣe lóòní
Ìbá dára kó o músé rẹ
Lọ́ọ̀ kún kún dùn
O bá múra sí iṣẹ́
Koò ba dii ẹni ẹ̀yẹ àti ẹni pàtàkì
Lóla
O bàá ṣíṣẹ́ kárakára lóòwúrọ̀
Kíí ọjọ́ alẹ́ le fún ọ ní 'simi
Ọ̀lẹ! Òwúrọ̀ lọjọ́ ẹní má ríre
©' Jẹ́nyọ̀ Ẹniọlá

Comments

Post a Comment